Trending News
Monday, 29 April

MÁKINDÉ SE ÀYÍPADÀ ILẸ̀ KORÍKO NÍ ỌGBÀ ÀWỌN ONÍRÒYÌN DI ILÉ ÌDÓKÒWÒ KÁRÀKÁTÀ ÀTI ÌGBAFẸ́

30 March

Wùmí Ọlátúyì, Ibadan.



Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ ònímọ̀ ẹ̀rọ Sèyí Mákindé, ní ọjọ́ ajé ṣe ìyípadà ilẹ koríko di gbọ̀ngàn ilé ìdókòwò káràkátà ti ìgbàlódé. Gómìnà Mákindé tun gbó'ríyìn fún àwọn alákòóso láti fi irú ilẹ̀ bẹ́ẹ̀ pamọ́ lágbègbè ìyágankú.



Tí ó sọ̀rọ̀ nibi ayẹyẹ náà tí ówáyé ní gbọ̀ngàn àwọn oníròyìn tí ọwá ni īyágankú etí óse ojú fún Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, Amọ̀fin Abdul-Raheem Adébáyọ̀ Lawal, tí ó kí Alága àwọn oníròyìn ti ìpínlè Ọ̀yọ́, Olóyè Adémọ́lá Babalolá, fún iṣẹ́ takuntakun pẹ̀lú ìfi ọmọ èèyàn ṣe. Wípé inkan yìí kì bá tí wáyé tipẹ́.  Óse àlàyé síwájú pé Olóyè Adémọ́lá Babalolá jẹ́ ẹni tí ófẹ́ ilọ̀siwájú, ókí àwọn oníròyìn kú Orí ire lati ni irúfẹ́ ènìyàn bẹẹ. 



             \"\"



Igbákejì Gómìnà sọpé iṣẹ ìròyìn jẹ́ tí ọdára. Wípé tí kò bájẹ́ wípé òun jẹ́ Amọ̀fin òun ìbá jẹ́ oníròyìn.           



Alága àwọn oníròyìn ti ìpínlè Ọ̀yọ́, Olóyè Adémọ́lá Babalolá, ósọ̀rọ̀ o dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ fún àtìlẹ́yìn rẹ̀ láti ìgbà tí òun ti dé ipo Alága oníròyìn lati ọdún 2019.       



Nínú ọ̀rọ̀ ti ẹni tí  ósojú Àrẹ àwọn oníròyìn ti orílẹ-èdè Nàìjíríà, Alhaji Bọ́lájí Kareem, gbóríyìn fún Gómìnà ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ Òní ìmọ̀ ẹ̀rọ Sèyí Mákindé, fún ìpinnu ìdàgbàsókè isẹ́ ní ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́ àti àtìlẹ́yìn fún àwọn ẹgbẹ́ oníròyìn.



Àwọn  tí ó peju sí ayẹyẹ náà ni ara àwọn Kọmísánà ní  ìpínlẹ̀ ọ̀yọ́, ati awọn àgbà oníròyìn.

  • Previous Post

    Sango Fire Outbreak: Senator Sympathies With Victi..

Leave A Reply

Similar Stories

Stay Connected With Us